mail me lyrics Send Lyrics Updates into my email! (feedburner)

Ma gbadura; Emi mbebe n’nu re

Ma gbadura; Emi mbebe n’nu re
Fun gbogbo aini re igagbogbo.

Ma gbadura; labe eru ese,
Adura nri eje Jesu ti nsan.

Ma gbadura; b’ are tile mu o,
Adura ngbe wa s’eba ‘te Baba.

Ma gbadura; n’nu wahala aiye,
Adura l’o nfun okan n’ isimi.

Ma gbadura; b’ ayo ba yi o ka,
Adura nlu harp, o nkorin angel’.

Ma gbadura; b’awon t’o feran ku,
Adura mba won mu omi iye.

Gbogb’ ohun aiye y’o b’aiye koja,
Adura wa titi: ma gbadura. Amin.


  • All Artistes Index
  • Random Posts

    No comments:

    Post a Comment

    Newer Post Older Post Home