mail me lyrics Send Lyrics Updates into my email! (feedburner)

Enikan mbe to feran wa - Hymns

Enikan mbe t’ O feran wa,
A! O fe wa!
Ife Re ju ti yekan lo,
A! O fe wa!
Ore aiye nko wa sile,
B’ oni dun ola le koro,
Sugbon ore yi ko ntanni,
A! O fe wa!

Iye ni fun wa b’ a ba mo,
A! O fe wa!
Ro b’ a ti je ni gbese to,
A! O fe wa!
Eje Re l’ O si fi ra wa,
Nin’ aganju l’ O wa wa ri
O si mu wa wa s’ agbo Re
A! O fe wa!

Ore ododo ni Jesu,
A! O fe wa!
O fe lati ma bukun wa,
A! O fe wa!
Okan wa fe gbo ohun Re,
Okan wa fe lati sunmo,
On na ko si ni tan wa je,
A! O fe wa!

Looko Re l’a nri’ dariji,
A! O fe wa!
On O le ota wa sehin,
A! O fe wa!
On O pese ‘bukun fun wa ;
Ire l’ a O ma ri titi
On O fi mu wa lo s’ ogo.
A! O fe wa! Amin.



  • All Artistes Index
  • Random Posts

    No comments:

    Post a Comment

    Newer Post Older Post Home